2 Chronicles 6:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
jọ̀wọ́, gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dáríjì àwọn eniyan Israẹli, àwọn iranṣẹ rẹ. Tọ́ wọn sí ọ̀nà tí wọn yóo máa tọ̀, kí o sì jẹ́ kí òjò rọ̀ sí ilẹ̀ tí o fún àwọn eniyan rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ ji, ati ti Israeli enia rẹ, nigbati iwọ ba ti kọ́ wọn li ọ̀na rere na, ninu eyiti nwọn o ma rìn: ki o si rọ òjo si ilẹ rẹ, ti iwọ ti fi fun awọn enia rẹ ni ini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ nínú èyí tí wọn ó má a rìn, kí o sì rán òjò lórí ilẹ̀ tí o ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ fún ìní.