2 Chronicles 6:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbàkúùgbà tí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ yìí, tabi tí àjàkálẹ̀ àrùn bá bẹ́ sílẹ̀, tabi ọ̀gbẹlẹ̀, tabi ìrẹ̀dànù ohun ọ̀gbìn, tabi eṣú, tabi kòkòrò tíí máa jẹ ohun ọ̀gbìn; tabi tí àwọn ọ̀tá bá gbógun ti èyíkéyìí ninu àwọn ìlú wọn, irú ìyọnu tabi àìsàn yòówù tí ó lè jẹ́,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ìyan ba mu ni ilẹ, bi àjakalẹ-arun ba wà, bi irẹ̀danu ba wà, tabi eṣú ti njẹrun, bi awọn ọta wọn ba yọ wọn li ẹnu ni ilẹ ilu wọn; oniruru ipọnju tabi oniruru àrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-àrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, tàbí ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdù, irúgbà tàbí ẹlẹ́ǹgà, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá yọ wọ́n lẹ́nu nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú wọn, ohunkóhun, ìpọnjú tàbí àrùn lè wá,