2 Chronicles 6:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan, tabi ti gbogbo Israẹli, eniyan rẹ, lẹ́yìn tí olukuluku ti mọ ìṣòro ati ìbànújẹ́ rẹ̀, bí wọ́n bá gbé ọwọ́ adura wọn sókè sí ìhà ilé yìí,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Adura ki adura, tabi ẹ̀bẹ ki ẹ̀bẹ ti a ba ti ọdọ ẹnikẹni gbà, tabi ọdọ gbogbo Israeli enia rẹ, nigbati olukuluku ba mọ̀ ipọnju rẹ̀, ati ibanujẹ rẹ̀, ti o ba si tẹ́ ọwọ rẹ̀ mejeji siha ile yi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì olúkúlùkù mọ̀ nípa ìpọ́njú rẹ̀ àti ìbànújẹ́, tí ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé OLÚWA yìí.