2 Chronicles 6:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
gbọ́ láti ibùgbé rẹ lọ́run; kí o sì ṣe gbogbo ohun tí àjèjì náà bá ń tọrọ lọ́dọ̀ rẹ, kí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà láyé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ, bí àwọn eniyan rẹ tí ń ṣe, kí wọ́n lè mọ̀ pé ilé ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ, ni ilé tí mo kọ́ yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ ki o gbọ́ lati ọrun, ani lati ibugbe rẹ wá, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti alejo na kepe ọ si; ki gbogbo enia aiye ki o le mọ̀ orukọ rẹ, ki nwọn ki o si le ma bẹ̀ru rẹ̀, bi Israeli enia rẹ, ki nwọn ki o le mọ̀ pe orukọ rẹ li a npè mọ ile yi ti emi kọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nigbà náà, gbọ́ láti ọ̀run àni láti ibi ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe ohun tí àwọn àlejò béèrè lọ́wọ́ rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo àwọn ènìyàn ayé kí wọn lè mọ orúkọ rẹ kí wọn sì bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ ti se, kí wọn kí ó sì lè mọ̀ wí pé ilé yìí tí èmi ti kọ, orúkọ rẹ ni ó ń jẹ́.