2 Chronicles 6:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá lọ sójú ogun, níbikíbi tí o bá rán wọn, láti lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jà, tí wọ́n bá kọjú sí ìhà ìlú tí o ti yàn yìí ati sí ìhà ilé tí mo kọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ yìí,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi awọn enia rẹ ba jade lọ si ogun si ọta wọn li ọ̀na ti iwọ o rán wọn, ti nwọn ba si gbadura si ọ, siha ilu yi, ti iwọ ti yàn, ati ile ti emi ti kọ́ fun orukọ rẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá lọ sójú ogun lórí àwọn ọ̀ta wọn, nígbàkígbà tí o bá rán wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ lórí ìlú yìí tí ìwọ ti yàn àti ilé OLÚWA tí èmi ti kọ́ fún orúkọ rẹ.