2 Chronicles 6:36 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ (nítorí pé kò sí ẹni tí kì í ṣẹ̀), tí inú bá bí ọ sí wọn, tí o sì mú kí àwọn ọ̀tá wọn ṣẹgun wọn, tí wọ́n sì kó wọn lẹ́rú lọ sí ọ̀nà jíjìn tabi nítòsí,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi nwọn ba ṣẹ̀ si ọ (nitoriti kò si enia kan ti kì iṣẹ̀,) bi iwọ ba si binu si wọn, ti o si fi wọn le awọn ọta lọwọ, ti nwọn ba si kó wọn ni igbekun lọ si ilẹ ti o jìna rére, tabi ti o wà nitosi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà tí wọ́n bá sì dẹ́sẹ̀ sí ọ-nítorí kò sí ènìyàn kan tí kò dẹ́sẹ̀-bí o bá sì bínú sí wọn tí o bá sì fi wọ́n fún àwọn ọ̀tá, tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré tàbí nítòsí,