2 Chronicles 6:37 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
sibẹ, tí wọ́n bá ranti, tí wọ́n sì ronupiwada ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n bá bẹ̀bẹ̀ tí wọ́n sọ pé, ‘àwọn ti ṣẹ̀, àwọn ti hu ìwà tí kò tọ́, àwọn sì ti ṣe burúkú,’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn, bi nwọn ba rò inu ara wọn wò, ni ilẹ nibiti a gbe kó wọn ni igbekun lọ, ti nwọn ba si yipada, ti nwọn ba si gbadura si ọ li oko ẹrú wọn, wipe, Awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣìṣe, awa si ti ṣe buburu;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n, nígbà tí, wọ́n bá sì yí ọkàn wọn padà ní ilẹ̀ tí wọ́n ti mú wọn ní ìgbèkùn, tí wọ́n sì ronú pìwàdà tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn, wọn ó sì wí pé, Àwa ti dẹ́sẹ̀, àwa sì ti ṣe ohun tí kò dára, a sì ti ṣe búburú.