2 Chronicles 6:41 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun, dìde, lọ sí ibùjókòó rẹ, ìwọ ati àpótí ẹ̀rí agbára rẹ. Gbé ìgbàlà rẹ wọ àwọn alufaa rẹ bí ẹ̀wù, kí o sì jẹ́ kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ yọ̀ ninu ire rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, dide, Oluwa Ọlọrun si ibi isimi rẹ, iwọ ati apoti agbara rẹ; jẹ ki a fi igbala wọ̀ awọn alufa rẹ, Oluwa Ọlọrun, ki o si jẹ ki awọn enia ayanfẹ rẹ ki o ma yọ̀ ninu ire.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí dìdé, OLÚWA Ọlọ́run mi, sí ibi ìsinmi rẹ, ìwọ àti àpótí ẹ̀rí agbára rẹ. Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, OLÚWA Ọlọ́run mi, kí o wọ̀ wọ́n lásọ pẹ̀lú ìgbàlà, jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ kí inú wọn kí ó dùn nínú ilé rẹ.