2 Chronicles 6:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
‘Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn eniyan jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, n kò tíì yan ìlú kankan ninu ẹ̀yà Israẹli láti kọ́ ilé sí fún ìjọ́sìn ní orúkọ mi, bẹ́ẹ̀ ni n kò yan ẹnìkan kan láti jẹ́ olórí àwọn eniyan mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati ọjọ ti emi ti mu awọn enia mi jade kuro ni ilẹ Egipti, emi kò yàn ilu kan ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli lati kọ́ ile, ki orukọ mi ki o wà nibẹ; bẹ̃ni emi kò yàn ọkunrin kan lati ṣe olori Israeli awọn enia mi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, èmi kò yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, láti kọ́ ilé, kí orúkọ mi kí ó lè wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yan ẹnikẹ́ni láti jẹ́ olórí lórí Ísirẹ́lì ènìyàn mi.