2 Chronicles 7:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Solomoni parí adura rẹ̀, iná kan ṣẹ́ láti ọ̀run, ó jó gbogbo ẹbọ sísun ati ọrẹ, ògo OLUWA sì kún inú tẹmpili.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
BI Solomoni si ti pari adura igbà, iná bọ́ lati ọrun wá, o si jo ọrẹ sisun ati ẹbọ na run; ogo Oluwa si kún ile na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Sólómónì sì ti parí àdúrà, iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó ọrẹ sísun àti ẹbọ, ògo Ọlọ́run sì kún ilé OLÚWA.