2 Chronicles 7:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kẹtalelogun oṣù keje, Solomoni ní kí àwọn eniyan máa pada lọ sílé wọn. Inú wọn dùn nítorí ohun rere tí OLUWA ṣe fún Dafidi, ati Solomoni ati gbogbo Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati li ọjọ kẹtalelogun oṣù keje, o rán awọn enia pada lọ sinu agọ wọn, pẹlu ayọ̀ ati inudidùn nitori ore-ọfẹ ti Oluwa ti fi hàn fun Dafidi, ati fun Solomoni, ati fun Israeli, enia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kẹtàlélógún (23rd day) tí oṣù kéje, ó sì rán àwọn ènìyàn padà sí ilé wọn, pẹ̀lú ayọ̀ àti ìdùnnú nínú wọn fún ohun rere tí OLÚWA ti ṣe fún Dáfídì àti Sólómónì, àti fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì.