2 Chronicles 7:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
n óo fà yín tu kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fun yín bí ẹni fa igi tu. N óo sì kọ tẹmpili yìí, tí mo ti yà sí mímọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ mi sílẹ̀, nítorí pé yóo di ohun ẹ̀gàn ati àmúpòwe láàrin gbogbo eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni emi o fà wọn tu ti-gbongbo-ti-gbongbo kuro ni ilẹ ti emi ti fi fun wọn; ati ile yi, ti emi ti yà si mimọ́ fun orukọ mi, li emi o ta nù kuro niwaju mi, emi o si sọ ọ di owe, ati ọ̀rọ-ẹgan larin gbogbo orilẹ-ède.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni èmi yóò fa Ísírẹ́lì tu kúrò láti ilẹ̀ mi, èyí tí èmi ti fi fún wọn, èmi yóò sì kọ̀ ilé náà sílẹ̀ èyí tí èmi ti yà sọ́tọ̀ fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ṣe ọ̀rọ̀ òwe, n ó fi ṣe ẹlẹ́yà láàrin gbogbo ènìyàn,