2 Chronicles 7:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Tẹmpili yìí gbayì gidigidi nisinsinyii, ṣugbọn nígbà náà, àwọn ẹni tó bá ń rékọjá lọ yóo máa sọ tìyanu-tìyanu pé, ‘Kí ló dé tí Ọlọrun fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí ati sí tẹmpili yìí?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ile yi, ti o ga, yio di ohun iyanu fun gbogbo ẹni ti o gba ibẹ kọja; tobẹ̃ ti yio si wipe, ẽṣe ti Oluwa fi ṣe bayi si ilẹ yi, ati si ile yi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti ní gbogbo àyíká ilé yìí nísinsinyí, bẹ́ẹ̀ ni yóò di ohun ìtànjẹ; gbogbo àwọn tí ó bá sì kọjá níbẹ̀ ni yóò jáláyà, wọn yóò sì wí pé, ‘Kí ni ó dé tí OLÚWA fì ṣe irú èyí sí ilẹ̀ yí àti sí ilé yìí?’