2 Chronicles 7:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn eniyan yóo dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọ́n kọ OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀, tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n ń lọ bọ oriṣa, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún wọn. Ìdí nìyí tí ibi yìí fi bá wọn.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A o si dahùn wipe, Nitori ti nwọn kọ̀ Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, Ẹniti o mu wọn ti ilẹ Egipti jade wá, ti nwọn si di ọlọrun miran mu, ti nwọn si bọ wọn, ti nwọn si sìn wọn: nitorina li o ṣe mu gbogbo ibi yi ba wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé: ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ OLÚWA sílẹ̀, Ọlọ́run baba wọn ẹni tí ó mú wọn jáde láti Éjíbítì wá, wọ́n sì ti fi ọwọ́ gba Ọlọ́run mìíràn mọ́ra, wọ́n bọ wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyí tí ó fi mú gbogbo ìjàǹbá náà wá sórí wọn.’ ”