2 Chronicles 7:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn alufaa dúró ní ipò wọn, àwọn ọmọ Lefi náà dúró láti kọrin sí OLUWA pẹlu ohun èlò orin tí Dafidi ṣe ati ìlànà tí ó fi lélẹ̀ láti máa fi kọrin ọpẹ́ sí OLUWA pé, “Ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ wà títí lae;” ní gbogbo ìgbà tí Dafidi bá lò wọ́n láti kọrin ìyìn. Àwọn alufaa yóo máa fọn fèrè gbogbo eniyan yóo sì dìde dúró.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn alufa duro lẹnu iṣẹ wọn; awọn ọmọ Lefi pẹlu ohun-ọnà orin Oluwa, ti Dafidi ọba ti ṣe lati yìn Oluwa, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai, nigbati Dafidi nkọrin iyìn nipa ọwọ wọn; awọn alufa si fùn ipè niwaju wọn, gbogbo Israeli si dide duro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn àlùfáà dúró ní àyè wọn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Léfì ti ṣe pẹ̀lú ohun èlò orin OLÚWA, tí ọba Dáfídì ti ṣe fún ìyìn OLÚWA àti tí á lò nígbà tí ó dúpẹ́, wí pé, “àànú rẹ̀ sì dúró láéláé,” níwájú àwọn ọmọ Léfì, àwọn àlùfáà sì fọn ipè, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dúró.