2 Chronicles 8:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Solomoni mú iyawo rẹ̀, ọmọ Farao kúrò ní ìlú Dafidi, lọ sí ibi tí ó kọ́ fún un. Ó ní, “Iyawo mi kò gbọdọ̀ máa gbé ààfin Dafidi, ọba Israẹli; nítorí pé ibikíbi tí àpótí OLUWA bá ti wọ̀, ó ti di ibi mímọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni si mu ọmọbinrin Farao gòke lati ilu Dafidi wá si ile ti o kọ́ fun u; nitori ti o wipe, Ni temi, obinrin kan kì yio gbe inu ile Dafidi, ọba Israeli, nitori mimọ́ ni ibi ti apoti-ẹri Oluwa ti de.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sólómónì gbé ọmọbìnrin Fáráò sókè láti ìlú Dáfídì lọ sí ibi tí ó ti kọ́ fún un, nítorí ó wí pé “Aya mi kò gbọdọ̀ gbé nínú ilé Dáfídì ọba Ísírẹ́lì nítorí ibi tí àpótí ẹ̀rí OLÚWA bá tí wọ̀, ibi mímọ́ ni.”