2 Chronicles 8:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ń rú ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Mose ti fi lélẹ̀, lojoojumọ, ati ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi, ati ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun ati àwọn àjọ̀dún mẹta pataki tí wọ́n gbọdọ̀ ṣe lọdọọdun: àjọ àìwúkàrà, àjọ ìkórè ati àjọ ìpàgọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ani nipa ilana ojojumọ, lati ma rubọ gẹgẹ bi aṣẹ Mose, li ọjọjọ isimi, ati li oṣoṣu titun, ati ajọ mimọ́, lẹ̃mẹta li ọdun, ani li ajọ aiwukara, li ajọ ọsẹ-meje, ati li ajọ ipagọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa ìlànà ojojúmọ́ fún ẹbọ rírú tí a pa lásẹ láti ọ̀dọ̀ Mósè wá fún ọjọ́ ìsinmi, oṣù tuntun àti lẹ́rìn mẹ́ta lọ́dún, ní àjọ àkàrà àìwú, ní àjọ ọ̀ṣẹ̀ méje àti àjọ ìpàgọ́.