2 Chronicles 8:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dafidi fi lélẹ̀, Solomoni pín àwọn alufaa sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn, ó sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí láti máa kọ orin ìyìn ati láti máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn alufaa ninu iṣẹ́ wọn ojoojumọ. Ó yan àwọn aṣọ́nà sí oríṣìíríṣìí ẹnu ọ̀nà gẹ́gẹ́ bí Dafidi eniyan Ọlọrun ti pa á láṣẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si yàn ipa awọn alufa, gẹgẹ bi ilana Dafidi baba rẹ̀, si ìsin wọn, ati awọn ọmọ Lefi si iṣẹ wọn, lati ma yìn, ati lati ma ṣe iranṣẹ niwaju awọn alufa, bi ilana ojojumọ: ati awọn adèna pẹlu ni ipa ti wọn li olukuluku ẹnu-ọ̀na: nitori bẹ̃ni Dafidi, enia Ọlọrun, ti pa a li aṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní pípamọ́ pẹ̀lú ìlànà baba rẹ̀ Dáfídì, ó sì yan ipa àwọn àlùfáà fún iṣẹ́ wọn àti àwọn ọmọ Léfì láti jẹ́ adarí láti máa yin àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìlànà ojojúmọ́. Ó sì tún yàn àwọn olùsọ́nà nípa pípín sí olúkúlùkù ẹnu ọ̀nà, nítorí èyí ni Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run ti paláṣẹ.