2 Chronicles 8:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Huramu fi àwọn ọkọ̀ ojú omi ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n mọ̀ nípa iṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi ranṣẹ, wọ́n lọ sí ilẹ̀ Ofiri pẹlu àwọn iranṣẹ Solomoni, wọ́n sì kó ojilenirinwo ati mẹ́wàá (450) ìwọ̀n talẹnti wúrà wá fún Solomoni ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Huramu si fi ọkọ̀ ranṣẹ si i, nipa ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn iranṣẹ ti o moye okun; nwọn si ba awọn iranṣẹ Solomoni lọ si Ofiri, lati ibẹ ni nwọn mu ãdọta-le-ni-irinwo talenti wura wá, nwọn si mu wọn tọ̀ Solomoni ọba wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Húrámù sì fi ọ̀kọ̀ ránsẹ́ sì i nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó mòye òkun. Èyí pẹ̀lú àwọn ènìyàn Sólómónì, lọ sí Ófírì wọ́n sì gbé àádọ́ta irinwó tálẹ́ntì wúrà wá, padà èyí tí wọ́n sì mú tọ ọba Sólómónì wá.