2 Chronicles 8:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn kò fi ipá kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ bí ẹrú, ṣugbọn ó ń lò wọ́n bíi jagunjagun, òṣìṣẹ́ ìjọba, balogun kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ninu awọn ọmọ Israeli ni Solomoni kò fi ṣe ọmọ-ọdọ fun iṣẹ rẹ̀; nitori awọn li ọga-ogun ati olori awọn onikẹkẹ́ rẹ̀ ati awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Solómónì kò mú ọmọ ọ̀dọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún Ísírẹ́lì, wọn jẹ́ ọ̀gágun rẹ̀, olùdarí àwọn oníkẹ̀kẹ́ àti olùdarí kẹ̀kẹ́.