2 Chronicles 9:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ọbabinrin ìlú Ṣeba gbọ́ nípa òkìkí Solomoni, ó wá sí Jerusalẹmu láti wá dán an wò pẹlu àwọn ìbéèrè tó le. Ó wá ninu ọlá ńlá rẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan ni wọ́n tẹ̀lé e lẹ́yìn, pẹlu àwọn ràkúnmí tí wọ́n ru oríṣìírìṣìí turari olóòórùn dídùn, ati ọpọlọpọ wúrà ati òkúta olówó iyebíye. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀ fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBATI ayaba Ṣeba gbọ́ òkiki Solomoni, o wá lati fi àlọ dan Solomoni wò ni Jerusalemu, pẹlu ẹgbẹ́ nlanla, ati ibakasiẹ ti o ru turari, ati wura li ọ̀pọlọpọ ati okuta iyebiye; nigbati o si de ọdọ Solomoni, o ba a sọ ohun gbogbo ti o wà li ọkàn rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ayaba Ṣébà gbọ́ nípa òkìkí Sólómónì, ó sì wá sí Jérúsálẹ́mù láti dán-an-wò pẹ̀lú ìbéèrè tí ó le. Ó dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ńlá kan pẹ̀lú ìbákasíẹ tí ó ru tùràrí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye wúrà, àti òkúta iyebíye, ó wá sí ọ̀dọ̀ Sólómónì ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn rẹ̀.