2 Chronicles 9:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn iranṣẹ Huramu ati àwọn iranṣẹ Solomoni tí wọ́n mú wúrà wá láti Ofiri, tún mú igi aligumu ati àwọn òkúta olówó iyebíye wá pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn iranṣẹ Huramu pẹlu, ati awọn iranṣẹ Solomoni ti o mu wura Ofiri wá, si mu igi-algumu, ati okuta iyebiye wá pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn Húrámù àti àwọn ọkùnrin Sólómónì gbé wúrà wá láti Ófírì, wọ́n sì tún gbé igi álígúmù pẹ̀lú àti òkúta iyebíye wá.