2 Chronicles 9:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Solomoni ọba fún ọbabinrin náà ní gbogbo ohun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́. Ẹ̀bùn tí ó fún un ju èyí tí òun alára mú wá lọ. Lẹ́yìn náà ọbabinrin náà pada lọ sí ìlú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni ọba si fun ayaba Ṣeba li ohun gbogbo ti o wù u, ohunkohun ti o bère, li aika eyiti o mu wa fun ọba. Bẹ̃ni o yipada, o si lọ si ilẹ rẹ̀, ati on ati awọn iranṣẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Sólómónì fún ayaba Ṣébà ní gbogbo ohun tí ó bèèrè fún àti ohun tí ó wù ú; ó sì fi fún un ju èyí tí ó mú wá fún un lọ. Nígbà náà ni ó lọ ó sì padà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìlú rẹ̀.