2 Chronicles 9:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìtẹ́ náà ní àtẹ̀gùn kan tí ó ní ìṣísẹ̀ mẹfa ati àpótí ìtìsẹ̀ kan tí a fi wúrà ṣe, tí a kàn mọ́ ìtẹ́. Igbọwọle wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ìtẹ́ náà, tí ère kinniun meji wà ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Àtẹgun mẹfa ni itẹ́ na ni, pẹlu apoti-itisẹ wura kan, ti a dè mọ itẹ́ na, ati irọpa ni iha mejeji ibi ijoko na, kiniun meji si duro lẹba awọn irọpa na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, àti pẹ̀lú àpóti ìtìsẹ̀ wúrà kan ni a dè mọ́ ọn. Ní ìhá méjèèjì ibi ìjókòó ní ó ní ìropá, pẹ̀lú kìnnìun tí ó dúró lẹ́bàá olúkúlùkù wọn.