2 Chronicles 9:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wúrà ni wọ́n fi ṣe gbogbo ife Solomoni, ati gbogbo ohun èlò tí ó wà ní ilé Igbó Lẹbanoni. Fadaka kò jámọ́ nǹkankan ní àkókò ìjọba Solomoni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo ohun-elo mimu Solomoni ọba jẹ wura, ati gbogbo ohun-elo ile igbo Lebanoni, wura daradara ni: kò si ti fadakà; a kò kà fadakà si nkankan li ọjọ Solomoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ohun èlò mímú ìjọba Solómónì ni ó jẹ́ kìkì wúrà, àti gbogbo ohun èlò agbo ilé ní ibi igbó Lébánonì ni ó jẹ́ wúrà mímọ́. Kò sì sí èyí tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì.