2 Chronicles 9:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé, ọba ní àwọn ọkọ̀ ojú omi tí àwọn iranṣẹ Huramu máa ń gbé lọ sí Taṣiṣi. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún mẹta ni àwọn ọkọ̀ náà máa ń dé; wọn á máa kó wúrà, fadaka, eyín erin, ati oríṣìíríṣìí àwọn ọ̀bọ ati ẹyẹ ọ̀kín wá sílé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori awọn ọkọ̀ ọba nlọ si Tarṣiṣi pẹlu awọn iranṣẹ Huramu; ẹ̃kan li ọdun mẹta li awọn ọkọ̀ Tarṣiṣi ide, nwọn nmu wura, ati fadakà, ati ehin-erin, ati inaki, ati ẹiyẹ-ologe wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba ní ọkọ̀ tí a fi ń tajà tí àwọn ọkùnrin Húrámù ń bojútó. Ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ó máa ń padà, ó ń gbé wúrà àti fàdákà àti eyín erin, àti ìnàkí àti ẹyẹ ológe wá.