2 Chronicles 9:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Solomoni ọba ní ẹgbaaji (4,000) ilé fún ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun, ó ní ẹgbaafa (12,000) ẹlẹ́ṣin. Ó kó àwọn kan sí àwọn ìlú tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sí, ó kó ìyókù sí Jerusalẹmu, níbi tí ọba ń gbé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni si ni ẹgbaji ile fun ẹṣin ati kẹkẹ́, ati ẹgbafa ẹlẹṣin, ti o fi si awọn ilu kẹkẹ́, ati ọdọ ọba ni Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sólómónì sì ní ẹgbàajì ilé fún àwọn ẹsin àti kẹ̀kẹ́, àti ẹgbàfà àwọn ẹsin (12,000), tí ó ba mọ́ nínú ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ nínú Jérúsálẹ́mù.