2 Chronicles 9:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
oúnjẹ tí ó wà lórí tabili rẹ̀ ati bí àwọn ìjòyè rẹ̀ ti jókòó, àwọn iranṣẹ rẹ̀, ìwọṣọ ati ìṣesí wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀ ati ìwọṣọ wọn, ati ẹbọ sísun tí ó ń rú ní ilé OLUWA, ẹnu yà á lọpọlọpọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati onjẹ tabili rẹ̀, ati ijoko awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iduro awọn iranṣẹ rẹ̀, ati aṣọ-wiwọ̀ wọn; ati awọn agbọti rẹ̀ pẹlu aṣọ-wiwọ̀ wọn, ati àtẹgun ti o mba gòke lọ si ile Oluwa; kò si kù agbara kan ninu rẹ̀ mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì rẹ̀, àti ìjòkòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti dídúró àwọn ìránṣẹ́ nínú aṣọ wọn, àti àwọn agbọ́tí nínú aṣọ wọn àti ẹbọ ọrẹ sísun tí ó ṣe ní ilé OLÚWA, ó sì ní ìdálágara.