2 Chronicles 9:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N kò gba ohun tí wọ́n sọ fún mi gbọ́ títí tí mo fi dé ìhín, tí èmi gan-an sì fi ojú ara mi rí i. Ohun tí wọ́n sọ fún mi kò tó ìdajì ọgbọ́n rẹ, ohun tí mo rí yìí pọ̀ ju ohun tí wọ́n sọ fún mi lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi kò gba ọ̀rọ wọn gbọ́, titi mo fi de, ti oju mi si ti ri i; si kiyesi i, a kò rò idaji titobi ọgbọ́n rẹ fun mi; nitori ti iwọ kọja òkiki ti mo ti gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n èmi kò gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́ àyàfi ìgbà tí mó dé ibí tí mo sì ri pẹ̀lú ojú mi. Nítòótọ́, kì í tilẹ̀ ṣe ìdàjọ́ ìdajì títóbi ọgbọ́n rẹ ní a sọ fún mi: ìwọ ti tàn kọ já òkìkí tí mo gbọ́.