2 Chronicles 9:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ògo ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ, tí inú rẹ̀ dùn sí ọ, tí ó gbé ọ gorí oyè láti jọba ní orúkọ rẹ̀. Ó ní ìfẹ́ sí Israẹli, ó fẹ́ fi ìdí wọn múlẹ̀ títí lae; nítorí náà, ó fi ọ́ jọba lórí wọn, láti máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olubukún li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o fẹran rẹ lati gbé ọ ka ori itẹ́ rẹ̀ lati ṣe ọba fun Oluwa Ọlọrun rẹ: nitoriti Ọlọrun rẹ fẹran Israeli lati fi idi wọn kalẹ lailai, nitorina ni o ṣe fi ọ jọba lori wọn, lati ṣe idajọ ati otitọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìyìn lóyẹ fún OLÚWA Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn nínú rẹ tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ láti jẹ ọba fún OLÚWA Ọlọ́run rẹ. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run rẹ fún Ísírẹ́lì láti fi ìdí wọn kalẹ̀ láéláé, ó sì ti fi ọ́ ṣe ọba lórí wọn, láti ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́.”