2 Corinthians 1:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo fi Ọlọrun jẹ́rìí ohun tí n óo sọ yìí. Mo sì fi ẹ̀mí mi búra! Ìdí tí n kò fi wá sí Kọrinti mọ́ ni pé n kò fẹ́ yọ yín lẹ́nu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si pè Ọlọrun ṣe ẹlẹri li ọkàn mi pe, nitori lati dá nyin si li emi kò ṣe ti wá si Korinti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì pe Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́rìí ọkàn mi pé nítorí àtidá yín sí ní èmi kò ṣe padà sí Kọ́ríńtì.