2 Corinthians 1:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ẹni tí ó ń fún wa ní ìwúrí ninu gbogbo ìpọ́njú tí à ń rí, kí àwa náà lè fi ìwúrí fún àwọn tí ó wà ninu oríṣìíríṣìí ìpọ́njú nípa ìwúrí tí àwa fúnra wa ti níláti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti ntù wa ninu ni gbogbo wahalà wa, nipa itunu na ti a fi ntù awa tikarawa ninu lati ọdọ Ọlọrun wá, ki awa ki o le mã tù awọn ti o wà ninu wahala-ki-wahala ninu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa lè máa pẹ̀lú tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.