2 Corinthians 1:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn bí a bá wà ninu ìpọ́njú, fún ìwúrí ati ìgbàlà yín ni. Bí a bá ní ìwúrí, ẹ̀yin náà yóo ní ìwúrí; ìwúrí yìí yóo sì kọ yín ní sùúrù nígbà tí ẹ bá ń jẹ irú ìyà tí àwa náà ń jẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi a ba si npọ́n wa loju ni, o jasi bi itunu ati igbala nyin, ti nṣiṣẹ ni ifàiyarán awọn iya kannã ti awa pẹlu njẹ: tabi bi a ba ntù wa ninu, o jasi fun itunu ati igbala nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbi bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù làti mú yin ní irú ìfaradá ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́.