2 Corinthians 10:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí a kò gbọdọ̀ da ara wa mọ́ àwọn kan tí wọn ń yin ara wọn, tabi kí á fara wé wọn. Fúnra wọn ni wọ́n ṣe òṣùnwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn ara wọn, àwọn tìkalára wọn náà ni wọ́n sì ń fi ara wọn wé. Wọn kò lóye.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe awa kò daṣa ati kà ara wa mọ́, tabi ati fi ara wa wé awọn miran ninu wọn ti ńyìn ara wọn; ṣugbọn awọn tikarawọn jẹ alailoye nigbati nwọn nfi ara wọn diwọn ara wọn, ti nwọn si nfi ara wọn wé ara wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé àwa kò dáṣà láti ka ara wa mọ́, tàbí láti fí ara wa wé àwọn mìíràn nínú wọn tí ń yin ara wọn; ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn jẹ́ aláìlóye bí wọn ti ń fí ara wọn díwọ̀n ara wọ́n, tí wọ́n sì ń fí ara wọn wé ara wọn.