2 Corinthians 10:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
A kò gbọdọ̀ ṣe ìgbéraga pupọ ju bí ó ti yẹ lọ lórí iṣẹ́ àwọn ẹlòmíràn. A ní ìrètí pé bí igbagbọ yín ti ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni ipò wa pẹlu yín yóo máa ga sí i, gẹ́gẹ́ bí ààyè wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awa kò ṣogo rekọja ãlà wa, eyini ni lori iṣẹ ẹlomiran; ṣugbọn awa ni ireti pe, bi igbagbọ nyin ti ndagba si i, gẹgẹ bi àla wa awa o di gbigbega lọdọ nyin si i lọpọlọpọ,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, èyí nì, lórí iṣẹ́ elòmiràn, ṣùgbọ́n àwa ní ìrètí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ti ń dàgbà sí i, gẹ́gẹ́ bí ààlà wa, àwa ó dí gbígbéga lọ́dọ̀ yín sí i lọ́pọ̀lọpọ̀.