2 Corinthians 10:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nǹkan ti òde ara nìkan ni ẹ̀ ń wò! Bí ẹnikẹ́ni bá dá ara rẹ̀ lójú pé òun jẹ́ ti Kristi, kí ó tún inú ara rẹ̀ rò wò, nítorí bí ó ti jẹ́ ti Kristi, bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwa náà jẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin si nwò nkan gẹgẹ bi nwọn ti fi ara hàn lode. Bi ẹnikẹni ba gbẹkẹle ara rẹ̀ pe, ti Kristi li on iṣe, ẹ jẹ ki on ki o si tún rò eyi ninu ara rẹ̀ pe, bi on ti jẹ́ ti Kristi, gẹgẹ bẹ̃li awa pẹlu si jẹ́ ti Kristi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin sì ń wo nǹkan gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi hàn lóde. Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìgboyà nínú ara rẹ̀, ti Kírísítì ni òun, kí ó tún rò lẹ́ẹ̀kan si pé, bí òun ti jẹ́ ti Kírísítì, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwa pẹ̀lú jẹ́ ti Kírísítì.