2 Corinthians 11:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Iranṣẹ Kristi ni wọ́n? Tí n óo bá sọ̀rọ̀ bí ẹni tí orí rẹ̀ kò pé, mo jù wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ Kristi. Mo ti fi agbára ṣiṣẹ́ jù wọ́n lọ. Mo ti wẹ̀wọ̀n nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Wọ́n ti nà mí nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Ẹ̀mí fẹ́rẹ̀ bọ́ lẹ́nu mi ní ọpọlọpọ ìgbà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iranṣẹ Kristi ni nwọn bi? (emi nsọ bi aṣiwère) mo ta wọn yọ; niti lãlã lọpọlọpọ, niti paṣan mo rekọja, niti tubu nigbakugba, niti ikú nigbapupọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Iránṣẹ́ Kírísítì ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbákùúgbà, ní ti fífẹ́rẹ̀ kú nígbà púpọ̀.