2 Corinthians 11:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọpọlọpọ ìgbà ni mo wà lórí ìrìn àjò, tí mo wà ninu ewu omi, ewu lọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà, ewu láàrin àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ mi, ewu láàrin àwọn tíí ṣe Juu, ewu ninu ìlú, ewu ninu oko, ewu lójú òkun, ati ewu láàrin àwọn èké onigbagbọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni ìrin àjò nigbakugba, ninu ewu omi, ninu ewu awọn ọlọṣa, ninu ewu awọn ara ilu mi, ninu ewu awọn keferi, ninu ewu ni ilu, ninu ewu li aginjù, ninu ewu loju okun, ninu ewu larin awọn eke arakunrin;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìrìnàjò nígbákùúgbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní ihà, nínú ewu lójú òkun, nínú ewu láàárin àwọn èké arákùnrin.