2 Corinthians 11:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí ẹ̀ ń fi ààyè gba àwọn ẹlòmíràn tí wọn ń wá waasu Jesu yàtọ̀ sí bí a ti waasu rẹ̀, ẹ sì ń gba ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti kọ́ gbà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bi ẹniti mbọ̀ wá ba nwãsu Jesu miran, ti awa kò ti wasu rí, tabi bi ẹnyin ba gbà ẹmí miran, ti ẹnyin kò ti gbà ri, tabi ihinrere miran, ti ẹnyin kò ti tẹwọgbà, ẹnyin iba ṣe rere lati fi ara da a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí bí ẹnìkan bá wá tí ó sì wàásù Jésù mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù rí tàbí bí ẹ̀yin bá gba ẹ̀mí mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà, tí ẹ sì ti yára tẹ́wọ́ gbà á.