2 Corinthians 11:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín, tí mo ṣe aláìní, n kò ni ẹnikẹ́ni lára, àwọn arakunrin tí ó wá láti Masedonia ni wọ́n mójútó àwọn ohun tí mo ṣe aláìní. Ninu gbogbo nǹkan, mo ṣe é lófin pé n kò ní wọ̀ yín lọ́rùn, n kò sì ní yí òfin yìí pada!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati mo si wà pẹlu nyin, ti mo si ṣe alaini, emi kò jẹ́ ẹrù fun ẹnikẹni: nitoriti ohun ti mo ṣe alaini awọn ara ti o ti Makedonia wá fi kún u; ati ninu ohun gbogbo mo ti pa ara mi mọ́ ki emi maṣe jẹ ẹrù fun nyin, bẹ̃li emi ó si mã pa ara mi mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni: nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedóníà wá ti mú wá. Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀.