2 Corinthians 12:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ wò ó! Ẹẹkẹta nìyí tí mo múra tán láti wá sọ́dọ̀ yín. N kò sì ní ni yín lára. Nítorí kì í ṣe àwọn nǹkan dúkìá yín ni mo fẹ́ bíkòṣe ẹ̀yin fúnra yín. Nítorí kì í ṣe àwọn ọmọ ni ó yẹ láti pèsè fún àwọn òbí wọn. Àwọn òbí ni ó yẹ kí ó pèsè fún àwọn ọmọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, igba kẹta yi ni mo mura tan lati tọ̀ nyin wá; emi kì yio si jẹ oniyọnu fun nyin: nitoriti emi kò wá nkan nyin, bikoṣe ẹnyin tikaranyin: nitoriti kò tọ́ fun awọn ọmọ lati mã tò iṣura jọ fun awọn õbi wọn, bikoṣe awọn õbi fun awọn ọmọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kíyèsí i, ìgbà kẹta yìí ni mo múra tan láti tọ̀ yín wá: èmi kì yóò sì jẹ́ oníyọnu fún yín nítorí tí èmi kò wá nǹkan yín, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnra yín; nítorí tí kò tọ́ fún àwọn ọmọ láti máa to ìṣúra jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò se àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn.