2 Corinthians 12:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé nígbà ti mo bá dé, mo lè má ba yín ní irú ipò tí mo fẹ́, ati pé ẹ̀yin náà lè rí i pé n kò rí bí ẹ ti ń rò. Ẹ̀rù ń bà mí pé kí ohun tí n óo bá láàrin yín má jẹ́ ìjà ati owú jíjẹ, ibinu ati ìwà ọ̀kánjúwà, ọ̀rọ̀ burúkú ati ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga ati ìrúkèrúdò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ẹru mba mi pe, nigbati mo ba de, emi kì yio bá nyin gẹgẹ bi irú eyi ti mo fẹ, ati pe ẹnyin ó si ri mi gẹgẹ bi irú eyi ti ẹnyin kò fẹ: ki ija, owu-jijẹ, ibinu, ipinya, isọrọ-ẹni-lẹhin, ijirọsọ, igberaga, irukerudo, ki o má ba wà:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé, nígbà tí mo bá dé, èmi kì yóò bá yín gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí mo fẹ́, àti pé ẹ̀yin yóò sì rí mi gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí ẹ̀yin kò fẹ́: Kí ìjà, owú-jíjẹ, ìbínú, ìpínyà, ìsọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, ìjírọ̀sọ̀, ìfẹẹ́gẹ̀, ìrúkèrúdò, má bà à wà.