2 Corinthians 13:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìdí tí mo fi ń kọ gbogbo nǹkan wọnyi nígbà tí n kò sí lọ́dọ̀ yín ni pé nígbà tí mo bá dé, kí n má baà fi ìkanra lo àṣẹ tí Oluwa ti fi fún mi láti fi mú ìdàgbà wá, kì í ṣe láti fi wo yín lulẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori idi eyi, nigbati emi kò si, mo kọwe nkan wọnyi pe, nigbati mo ba de, ki emi ki o má bã lò ikannú, gẹgẹ bi aṣẹ ti Oluwa ti fifun mi fun idagbasoke, kì si iṣe fun iparun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìdí nìyí mo ṣe kọ̀wé àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá dé kí èmi má ba à lo ìkanra ní lílo àṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa ti fifún mí, láti mú dàgbàsókè, kì í ṣe láti fà yín subú.