2 Corinthians 13:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òtítọ́ ni pé a kàn án mọ́ agbelebu ní àìlera, ṣugbọn ó wà láàyè nípa agbára Ọlọrun. Òtítọ́ ni pé àwa náà jẹ́ aláìlera pẹlu rẹ̀, ṣugbọn a óo wà láàyè pẹlu rẹ̀ nípa agbára Ọlọrun ninu ìbálò wa pẹlu yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe a kàn a mọ agbelebu nipa ailera, ṣugbọn on wà lãye nipa agbara Ọlọrun. Nitori awa pẹlu jasi alailera ninu rẹ̀, ṣugbọn awa ó wà lãye pẹlu rẹ̀ nipa agbara Ọlọrun si nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé a kàn án mọ́ àgbélébùú nípa àìlera, ṣùgbọ́n òun wà láàyè nípa agbára Ọlọ́run. Nítorí àwa pẹ̀lú já sí aláìlera nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run sí yín.