2 Corinthians 13:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
À ń gbadura sí Ọlọrun pé kí ẹ má ṣe nǹkan burúkú kan, kì í ṣe pé nítorí kí á lè farahàn bí ẹni tí kò kùnà, ṣugbọn kí ẹ̀yin lè máa ṣe rere, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa dàbí ẹni tí ó kùnà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ awa ngbadura si Ọlọrun, ki ẹnyin ki o máṣe ibikibi kan; kì iṣe nitori ki awa ki o le fi ara hàn bi awọn ti a mọ̀ daju, ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mã ṣe eyi ti o dara, bi awa tilẹ dabi awọn ti a tanù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ àwa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí kí àwa lè farahàn bí àwọn ti ó tayọ̀, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè máa ṣe èyí tí ó dára bí àwa tilẹ̀ dàbí àwọn tí a tanù.