2 Corinthians 13:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà inú wa dùn nígbà tí àwa bá jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yin sì jẹ́ alágbára. Èyí ni à ń gbadura fún, pé kí ẹ tún ìgbé-ayé yín ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori awa nyọ̀, nigbati awa jẹ alailera, ti ẹnyin si jẹ alagbara: eyi li awa si ngbadura fun pẹlu, ani pipe nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí àwa ń yọ̀, nígbà ti àwa jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yín sì jẹ́ alágbára; èyí ni àwa sì ń gbàdúrà fún pẹ̀lú, àní pípé yín.