2 Corinthians 2:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó jẹ́ kí á lè wà ninu àjọyọ̀ ìṣẹ́gun tí Kristi ṣẹgun, nígbà gbogbo. Ọlọrun náà ni ó tún ń mú kí ìmọ̀ rẹ̀ tí ń jáde láti ara wa máa gba gbogbo ilẹ̀ káàkiri bí òórùn dídùn níbi gbogbo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun, ẹniti nyọ̀ ayọ iṣẹgun lori wa nigbagbogbo ninu Kristi, ti o si nfi õrùn ìmọ rẹ̀ hàn nipa wa nibigbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí wá nígbà gbogbo nínú Kírísítì, tí a sì ń fi òórùn ìmọ̀ rẹ̀ hàn nípa wa níbi gbogbo.