2 Corinthians 2:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí àwa kì í ṣe àwọn tí ń ba ọ̀rọ̀ Ọlọrun jẹ́ nítorí èrè tí wọn óo rí jẹ níbẹ̀, bí ọpọlọpọ tí ń ṣe. Ṣugbọn à ń waasu pẹlu ọkàn kan bí eniyan Kristi, ati gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Ọlọrun rán níṣẹ́, tí ó ń ṣiṣẹ́ níwájú Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori awa kò dabi awọn ọ̀pọlọpọ, ti mba ọ̀rọ Ọlọrun jẹ́: ṣugbọn bi nipa otitọ inu, ṣugbọn bi lati ọdọ Ọlọrun wá, niwaju Ọlọrun li awa nsọ̀rọ ninu Kristi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí àwa kò dàbí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí ń fí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣòwò jẹun; ṣùgbọ́n nínú òtítọ́ inú àwa ń sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọ́run nínú Kírísítì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.