2 Corinthians 4:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kì í ṣe àwọn nǹkan tí a lè fi ojú rí ni a tẹjúmọ́, bíkòṣe àwọn nǹkan tí a kò lè fi ojú rí. Nítorí àwọn nǹkan tí yóo wà fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn nǹkan tí a lè fi ojú rí. Àwọn nǹkan tí a kò lè fi ojú rí ni yóo wà títí laelae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Niwọn bi a kò ti wò ohun ti a nri, bikoṣe ohun ti a kò ri: nitori ohun ti a nri ni ti igba isisiyi; ṣugbọn ohun ti a kò ri ni ti aiyeraiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níwọ̀n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.