2 Corinthians 4:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A ti kọ àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ tíí máa ti eniyan lójú sílẹ̀. A kò hùwà ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni a kò yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ṣugbọn ọ̀nà tí a fi gba iyì ninu ẹ̀rí-ọkàn eniyan ati níwájú Ọlọrun ni pé à ń fi òtítọ́ hàn kedere.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awa ti kọ̀ gbogbo ohun ìkọkọ ti o ni itiju silẹ, awa kò rìn li ẹ̀tan, bẹ̃li awa kò fi ọwọ́ ẹ̀tan mu ọ̀rọ Ọlọrun; ṣugbọn nipa fifi otitọ hàn, awa nfi ara wa le ẹri-ọkàn olukuluku enia lọwọ niwaju Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwa tí kọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ tí ó ní ìtìjú sílẹ̀, àwa kò rìn ní ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò fi ọwọ́ ẹ̀tàn mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n nípa fífí òtítọ́ hàn, àwa ń fí ara wa le ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù ènìyàn lọ́wọ́ níwájú Ọlọ́run.